Lojuna lati jẹ ki imugbooro ba iṣẹ ati ọja wọn, ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited tun ti tọwọ bọwe adehun nipa ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu ileeṣẹ Niger Foods Breeding and Feedlot Center. Nibi abẹwo ti alaṣẹ ati oludasilẹ Adron Homes, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ṣe lọ si ileeṣẹ naa laipẹ yii, ni wọn ti fẹnuko lori adehun tuntun ọhun. Igbesẹ yii ko ṣai waye, bi ko ṣe lati ṣe agbelarugẹ fun iṣẹ…
Ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lo tun ti gbarada nibi akanṣe eto ti wọn pe ni Africa ESG Conference and Nigeria Project Expo , ti ọdun 2026. Ipade naa, ẹlẹkẹwaa iru rẹ lo waye laipẹ yii, nibi ti awọn agbaagba nidi idasilẹ okoowo kaakiri ilẹ Afrika ti peju. Awọn oludaṣẹsilẹ, aṣoju ijọba, olori ileeṣẹ ati awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka to n ri si dukia, ile kikọ, iṣẹ akanṣe ati eto iṣuna ko gbẹyin…
Gbogbo ilu Ilaro nipinlẹ Ogun ni wọn gbalejo awọn gbajugbaja nidi iṣẹ tiata nilẹ Naijiria, paapaa ẹka ti Yoruba. Ko sohun meji to fa a, bi ko ṣe ti eto isinku ilu mọ-ọn ka nni, Taiwo Hassan tọpọ awọn eeyan mọ si Ogogo. Ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni Ogogo jade laye lẹyin aisan jẹjẹrẹ ipele kẹrin, eyi ti awọn oloyinbo n pe ni "State Four Cancer". Ọsẹ diẹ sẹyin ni wọn sọ pe aisan…
Aarẹ ẹgbẹ awọn akẹkọọjade nile ẹkọ girama ti Remo Secondary School Old Students Association (RSSOSA) niluu Sagamu, Aarẹ Adetola EmmanuelKing ti gbe oṣuba kare fun igbakeji rẹ, ẹka tilẹ Gẹẹsi, Ọgbẹni Damola Aiyeola lori ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun. Aarẹ EmmanuelKing lo gbe oṣuba kare naa ninu atẹjade to fi ranṣẹ si Aiyeola. Ninu atẹjade ọhun, Aarẹ EmmanuelKing to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ…
Gomina ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan fun igbakeji nipinlẹ Ọṣun, Ademola Adeleke ti gbe iwe ẹri moyege ti ajọ eleto idibo, INEC fa le e lọwọ, gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina lọ ba Aarẹ Bọla Tinubu. Ile agbara ilẹ Naijiria, Aso Rock ni Adeleke ti lọ gbe iwe ẹri naa fun Aarẹ Tinubu
Oludije sipo aarẹ Naijiria labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Party, ADC, Atiku Abubakar ti sọ pe ọdun 2027 ni yoo jẹ ọdun to gbẹyin foun lati dije fun ipo aarẹ. Atiku to ti n dije fun ipo aarẹ lati ọdun 2007 lo sọ eyi lasiko to n dahun ibeere laipẹ yii. Atiku sọ pe boun ko ba ti wọle sipo aarẹ Naijiria lọdun, 2027, oun yoo gba ipo naa patapata. O ni ko si erongba lati dije fun ipo aarẹ lọdun…
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii lawọn mọlẹbi oloogbe ọkunrin kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Oluṣẹgun Ṣobiye ṣi n bẹbẹ fun idajọ ododo, lori bi wọn ṣe pa a. Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ ṣe sọ, wọn ni alaga ẹgbẹ awọn to n tun ọkọ ṣe, eyi ti wọn pe ni Nigeria Automobile Techinician Association, ẹka ti agbegbe Oke-Mọsan niluu Abẹokuta, Kẹhinde Amidu lu Ṣobiye pa. Ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ to kọja…
Alaṣẹ ati oludasile ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited nilẹ Naijiria, Aare Adetola EmmanuelKing ti gbe oṣuba kare fun Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun lori akitiyan ati ipa to n ko lẹka eto ẹkọ. Aarẹ EmmanuelKing lo gbe oṣuba naa nibi ayẹyẹ ikẹkọọjade awọn akẹkọọ saa ọdun 2026 nile ẹkọ girama ti RSS, iyẹn Remo Secondary School (RSS) to wa niluu Sagamu, ipinlẹ Ogun. Ara ọtọ ni ayẹyẹ…
Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ ijihinrere ti ẹmi ti INRI (INRI Evangelical Spiritual Church) Wolii Elijah Babatunde Ayọdele, ti sọ pe ẹnikẹni ti wọn ba ka iwa ọdaran igbesunmọmi ati ijinigbe mọ lọwọ yẹ ki wọn pa wọn loju ẹsẹ ni, kii ṣe pe ki wọn foju wọn ba ile-ẹjọ. Wolii Ayọdele rọ ijọba apapọ lati fagile gbigbe awọn ajinigbe ati awọn agbesunmọmi lọ sile-ẹjọ lojuna lati jẹ ki wọn jiya ẹṣẹ wọn. Ninu…
Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni ọga agba pata fun ileeṣẹ eleto aabo nipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun State Community, Social Orientation and Safety Corps, ti ọpọ mọ si So-Safe Corps, Oluṣọji Ganzallo, ti sọrọ lori bi ipinlẹ Ogun ṣe n ṣe aṣeyọri lori eto aabo ẹmi ati dukia araalu. Ọga agba naa sọ pe ko si ọgbọn alumọkọroyii kan tawọn n da, bi ko ṣe ifiọwọsowọ pọ lati rii daaju pe eto aabo ko mẹhẹ ni ipinlẹ naa. …
Ipinlẹ Ogun ko nii pẹẹ di ọkan ninu awọn ipinlẹ to lowo julọ ni Naijiri bayii pẹlu bi wọn ṣe ti bẹrẹ sii wa epo rọbi ni ipinlẹ naa bayii lẹyin ti wọn ti ṣawari ohun alumọọni ọhun lọna meji ọtọọtọ nibẹ. Oludamọran fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun tii ṣe Gomina Ipinlẹ Ogun lori Eto Iroyin ati Ọgbọn Atinuda, Ọgbẹni Kayọde Akinmade lo fìdí iroyin yii mulẹ lasiko to gba awọn to n fi ede Yoruba kọroyin ni ipinlẹ…
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdu ti fi igbagbọ ẹ han pe awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin to wa kaakiri ipinlẹ lorileede yoo gba aba idasilẹ lori awọn ọlọpaa ibilẹ wọle, nitori oun nikan lọna abayọri sawọn isoro to n dojukọ eto abo to mẹhẹ. O sọrọ yii nigba to n kopa nibi eto tẹlifisan, ipade ilu,o ni igbesẹ ti n lọ lọwọ lori ọna bi idasilẹ ọlọpaa ọhun yoo ṣe di amulo. O wa gboriyin fun Aarẹ Bọla…
Gbajumọ oloṣelu, nipinlẹ Ogun, Oloye Ṣẹgun Ṣowunmi lo sọrọ yii lasiko ti ẹgbẹ oniroyin lede Yoruba nilẹ Naijiria, League of Yoruba Media Practitioners ṣabẹwo si i nilẹ rẹ nilu Abẹokuta. Ṣowunmi tun gboṣuba kare fun Aarẹ Tinubu fun awọn iṣẹ akanṣe aritọkasi to ti ṣe paapaa lẹka awọn ohun amayedẹrun. Gẹgẹ bi ọrọ rẹ, 'Bi ija ba wa nibẹ ka pari ẹ, Tinubu ṣiṣẹ to lapẹẹrẹ, eyi tawọn eeyan ma ranti fun…
Ẹgbẹ́ awon oniroyin ede Yoruba, iyen 'League of Yoruba Media Practitioners' (LYMP) ti fi oye baba egbe naa da agba oloselu ati akinkaju omo Yoruba, Oloye Olabode Ibiyinka George lola. Ojoruu, Wesidee to koja yii leto idanilola ohun waye. Egbe naa se eyi fun mimo riri ati atileyin ti baba fun egbe yii ati fun iran Yoruba lapapo. Ọ̀pọ̀ àwọn àlejò ló péjọ síbi idalola naa, eyi ti ko yo awon omo Oloye…